Hymn 773Yoruba
1. Ka sowo po, ka sowo po
Pelu ife Mimo
Ka gbadura nigba gbogbo
Ka teriba fun Oba Oluwa,
E ma we owo fun ara nyin
Pelu ’dapo Mimo.
2. E ma mura ninu ohun kan,
Ijo kan Mimo ni,
Ki ise pelu igberaga,
Eda aiye ko dara
E ma teriba fun ara nyin
Iteriba Mimo.
3. E ma se soro ibunu,
Ero buburu ko da
Ijo Mimo ninu ife ni,
E sin Oluwa pelu ife,
Pelu ife l’awon Angeli
Fi sin Baba l’Orun.
Amin
