Hymn 744Yoruba
1: Ẹyin anyanfẹ Mi
Mo de lati ba yin gbe,
Ẹ fi ayọ sunmọ Mi
2: Ẹ wo Ogo Ọrun
Ti awọn maleka
Sọkalẹ fun yin loni
3: Ẹnyin omo Ijọ mi
Ẹ ṣe ifẹ temi
Kayọ na le di mimọ
4: Ẹnyin akọrin mi
Wo ayọ to logo
Ti a gbe fun yin loni
5: Ẹnyin ayanfẹ Mi
Ẹ kọrin ninu ifẹ
Ki ẹ le gbade iye
6: Ẹ wo ogo na ntan
Si gbogbo agbaye
Ẹ jẹ kogo na le tan
7: Ogo Ọrun sọkalẹ
Lati ba ẹnyin ọmọ
Gbe li ọjọ oni
8: Ẹnyin Ijọ Mimọ
Wo iṣẹ ta gbe le ẹnyin
Ọmọ ẹmi lọwọ
9: Ẹ wo awọn akọrin
Ti nkọ mimọ sọba Iye
Ẹ jẹ ka ka yin mọ wọn,
10: Ẹ kiyesi ara
Ẹ wogo ta fun yin
Ki o le ba yin kalẹ
11: Halleluya lorin
Tawọn maleka nkọ
Fi yin Baba loke
12: Ẹ wo ade ogo
Ti awọn maleka
Sọkalẹ fun ẹnyin ọmọ.
13: Ẹ tọju aye na
Ti a ti pe yin si
Kẹ le jogun iye
14: a o tọju aye na
Ti a ti pe wa si
Ka le jogun iye.
Amin
