Hymn 554Yoruba
1. Baba ka mi mo won,
Ki n le j’ogun iye,
Ka mi mo awon ti orun
Ki n le j’ogun iye.
2. Se mi ni ayanfe,
Ki n le j’ogun iye
Baba se mi ni ayanfe
Ki n le j’ogun iye.
3. Enyin Ijo Mimo
Oko ‘kehin l’eyi
E mura giri lekoko
K’oko ‘kehin to kun
4. Enyin ayanfe mi,
E yin Mi lotito
E mura giri lati sin
Ke le j’ogun iye
5. Or’ofe Re Baba
Ko ba w’omo Re gbe
K’emi olutunu orun
Ko ma s’amona wa.
Amin
