Hymn 51Yoruba
1. Oluwa, Oluwa, Oluwa Olugbala
Awa Ijo Mimo la’torun wa.
Wa f’anu gbo ti wa.
2. Olugbala, Oluwa Olusegun,
Awa omo Re nkepe e O,
Wa gbo adura wa.
3. Enyin Ogun Mimo la’torun wa,
E wa lati sokanle sinu,
Ijo Mimo yi.
4. Enyin Angel’ e ho iho ayo
S’emi Oluwa mbe pelu enyin,
Ijo Mimo yi.
5. Fun wa lagbara sinu Ijo Mimo yi
Kawa lelo fun Ogo Re,
Laiye ainiekun.
6. Mura si ‘se ‘ise Olugbala
Nitori Ade Iye mbe f’enyin,
Lojo ikehin.
Amin
