Hymn 407Yoruba
1. Wa pelu wa, sure fun wa, oba Mimo
Se ri ‘bukun Re s’ori wa,
Ka ma bisi, ka ma re si, ni Ijo Mimo
K’Alleluya le j’orin wa.
2. Michael Mimo, gbe’da soke ka le bori
Gbogbo ota Ijo Mimo
K’o ko kehin le w’aiye mo lase Kristi,
Ka le jumo ke Hossanah.
3. Ka boyun bi, kawon agan towo b’osun
Ka ma rago, ka ma pose
Ka je sekun, l’alafia ninu ayo nla.
Ki Iye, Igbala je pin wa.
Amen
