CCC Hymn 244

1: Ọjọ agbara na ti ọsan doru

YorubaHoly Spirit
Hymn 244Yoruba
1: Ọjọ agbara na ti ọsan doru Tasọ ‘jọ mimọ kalẹ Irawọ meje loyọ si oke ọrun Awọn ẹyẹwo nke luli Awọn ẹyẹwo nke luli Luli ore ọfẹ Irawọ meje loyọ si oke ọrun Awọn ẹyẹwo nke luli 2: Osu kẹsan ọjọ kọkọndinlọgbọn Ọdun nineteen forty seven Ni eyi sẹlẹ lagogo mẹta ọsan Gbọwọ S.B.J. Ọshọfa Ch: Eyi lọkọ ikẹyin To sọkalẹ lat’ọrun Iye iye lohun na nke Fun ‘jọ mimọ Celestial 3: Isẹ lohun na nke ẹ mura sisẹ Siṣẹ pẹlu ‘fẹ mimọ Ere isẹ rẹ ni iwọ yio gba o Siṣẹ pẹlu ‘fẹ mimọ Ch: Ẹjẹka mura sisẹ Sisẹ pẹlu ifẹ mimọ Ere isẹ rẹ ni iwọ yio gba o Siṣẹ pẹlu ‘fẹ mimọ 4: Ẹjẹ kẹro wa le male tie mi Ninu eyi ni iye wa Nitori pero ara on ni iku Ninu emi ni ye wa Ch: ninu eyi ni iye wa Nitori pero ara on ni iku Ninu emi ni ye wa 5: Ero ara ọta loje s’Ọlọrun Idunnu Ọlọrun l’emi Iye awa to gba Jesu l’Oluwa Ẹjẹ ka sin ninu ifẹ Ch: Ẹjẹ ka sin ninu ifẹ Ẹ jẹ kajọ sowọpọ Iye awa to gbaa Jesu Ẹjẹ ka sin ninu ifẹ 6: Ifẹ lohun na nke Ẹjẹ ka lo ‘fẹ Bi iwe Mimọ ti wi Kọrintin ikini oori kẹtala Ifẹ lohun na kọ wa Bẹrẹẹ lati ẹsẹ ikini Titide iparirẹ Kọrintin ikini oori’ kẹtala Ifẹ lohun na kọ wa 7: Igbagbọ ni idaniloju ohun ti a nre ti Ijẹri ohun to a kori Oniyemeji ki yio ro ohunkohun gba Jesi Kristi to fun wa Ch: Ẹni bani Jesu ohun lohun bori aiye Oniyemeji ki yio ri ohunkohun gba Juse Kristi to funwa 8: Ẹjẹ ka tọrọ agbara isindopin Ibẹrẹ kọ lonisẹ Lawa le r’ode iye ati pese silẹ fun ijọ mimọ Ch: Ibẹrẹ kọ lonisẹ Bi kose asedopin Ẹjẹ ka sisẹ lati gbade ogo Ta pese fun Ijọ mimọ Hymns 247 – 250 are Reserved Orin Agbara