CCC Hymn 182

1. E KU ayo bla t'Ajinde

YorubaEaster
Hymn 182Yoruba
1. E KU ayo bla t'Ajinde T'Oluwa demi wa si d'oni, Ope f'Oluwa to da wa si d'oni, Ayo, ayo, wa ti po to, Pelu idapo t'awon Angeli. 2. E yo e yo, ninu Oluwa, E ke Kabiyesi s'Oba nla, Jesu Kristi bi Oba ojo oni, E yo, e yo fun 'gbala wa, T'a fi f'aiye ninu Eje Jesu. 3. E ke Hossanah si Oba wa, Oludande Agbaiye jinde, Jesu Kristi ni Oba ojo oni, Halleluya si Olorun, To f'omo Re fun 'gbala araiye. 4. Ijo Mimo e wole sin, Olugbala araiye jinde, Awon 'rawo Orun nyin logo, O ti j'Oba, Jesu joba agbaiye, E jumo sin Jesu. Amin