CCC Hymn 547

1: Mo rọ mọ agbelebu rẹ Jesu

YorubaFaith
Hymn 547Yoruba
1: Mo rọ mọ agbelebu rẹ Jesu Mo fi oun gbogbo silẹ fun ọ B’o ti wun ki ‘ji aiye pọ to Irẹ nikan ni mo mọ l’Olugbala 2: Mo rọ mọ agbelebu rẹ Jesu Ina ti njo ko le sunmọ mi Irẹ mikan ni mo mọ l’Olugbala 3: Mo rọ mọ agbelebu rẹ Jesu Ibẹru ko si fun mi mọ gbagbo B’ẹkun pẹ d’alẹ ayọ nbọ l’owurọ Irẹ mikan ni mo mọ l’Olupese 4: Mo rọ mọ agbelebu rẹ Jesu Gb’aiye mi ko si lo fun ogo rẹ K’pgo rẹ le han ninu aiye mi K’aiye le mọ pe “Rẹ nikan l’Ọba nla! 5: Mo rọ mọ agbelebu rẹ Jesu Ọba mo sina Irẹ lo wa mi ri Isun rẹ lo ṣe iwosan f’ẹsẹ mi Iyebiye, A! ẹjẹ t’o ra mi pada 6: Mo rọ mọ agbelebu rẹ Jesu Ayọ nla lo jẹ ‘gba mo mo gb’ohun rẹ Pe, wa ẹlẹsẹ sinu imọlẹ Imọlẹ t’aiye at’ọrun nsọ n’pa rẹ 7: Mo rọ mọ agbelebu rẹ Jesu Orin wo lo dun bi Halleluyah? Awọn Angeli lat’ ọdọ Baba Nyọ pẹlu wa Wọn nke Halleluyah! Orin Idajo