Hymn 410Yoruba
1: Bukun fun wa Oluwa
Gbewa ga Oluwa
Bukun fun wa Oluwa
Ninu ile mimọ Rẹ
Kawa le ri ogo Rẹ
Ogo rẹ ayeraye
Kaye le mọ daju pe Irẹ lo ran wa
2: Pese fun awa ọmọ rẹ
Awa ti nwoju rẹ
Ẹyẹ li oke ọrun
Irẹ lo bukun fun wọn
Ọba ayeraye
Sisura rere silẹ
Fun awa ti nse ayanfẹ Rẹ
Jehoẹah Jesu Kristi wa gbọ o
3: Ranti alairijẹ
Ranti alairimu
Awọn alailera
Awọ agan nwoju Rẹ
Ọba ti kin gbagbe
4: Ranti wa si rere
Bukun fun wa
Mase jẹ koju ti wa
Kawa le mu Ibukun ayọ lọ ‘le wa,
Amin
