CCC Hymn 410

1: Bukun fun wa Oluwa

YorubaBlessing
Hymn 410Yoruba
1: Bukun fun wa Oluwa Gbewa ga Oluwa Bukun fun wa Oluwa Ninu ile mimọ Rẹ Kawa le ri ogo Rẹ Ogo rẹ ayeraye Kaye le mọ daju pe Irẹ lo ran wa 2: Pese fun awa ọmọ rẹ Awa ti nwoju rẹ Ẹyẹ li oke ọrun Irẹ lo bukun fun wọn Ọba ayeraye Sisura rere silẹ Fun awa ti nse ayanfẹ Rẹ Jehoẹah Jesu Kristi wa gbọ o 3: Ranti alairijẹ Ranti alairimu Awọn alailera Awọ agan nwoju Rẹ Ọba ti kin gbagbe 4: Ranti wa si rere Bukun fun wa Mase jẹ koju ti wa Kawa le mu Ibukun ayọ lọ ‘le wa, Amin