CCC Hymn 316

1: Ẹyin Oluwa ọga ogo

YorubaPraises
Hymn 316Yoruba
1: Ẹyin Oluwa ọga ogo Ọpẹ iyin loyẹ fun Awọn angeli mimọ nsin Ọpẹ iyin loyẹ fun Ki iṣe ileri lai musẹ Nitori pe alanu ni Ọmọ ijọ mimọ ẹ sin Ọpẹ iyin loyẹ fun 2: Ẹgbe orukọ Oluwa ga Ọpẹ iyin loyẹ fun Onirobinujẹ nri wosan Ọpẹ iyin loyẹ fun Iyanu nla lorukọ Rẹ Ileri Rẹ wa titi lai Ogo fun Oluwa loke Ọpẹ iyin loyẹ fun 3: Gbogbo ohun alaye nyin Ọpẹ iyin loyẹ fun Kọrun ataye sọwipe Ọpẹ iyin loyẹ fun Iyanu lọba ijọ mimọ Ododo Rẹ wa titi lailai Ẹyin ọmọ ‘jọ mimọ ẹsin Ọpẹ iyin loyẹ fun. Amin